Eye Mejila
YO

Eye Mejila 歌詞

ジャンルAfrobeats
原文言語YO
閲覧数6
Aa表示設定
文字サイズ 18

原文歌詞

YO
翻訳はまだありません。原文を表示しています。
Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi Wọn mí kọ'rin, l' òwúrọ' tí mo jí Wọn mí kọ'rin ayọ Wọn mí kọ'rin ìwúrí Mo wá gbé'ra ní'lẹ', mo bọ'jú, bọ'nu Mo gbé àpamọ'wọ' mi, mo kó bàtà s'ẹsẹ Ojú mà mí ro mí, àárẹ m'ọ'kàn mi Ẹyẹ ó dá'nu dúró o, wọn mí kọ'rin Wọn mí kọ'rin ìgboyà Wọn mí kọ'rin ìṣítí Wọn ní Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o Mo ṣí ilẹkùn ilé, mo bọ' s'óde Mo rìn pàdé ẹbí, pẹ'l'álàdúgbò Mo fi tẹ'rìtẹ'rìn kí gbogbo wọn Mo mí kọ'rin ayọ Mo mí kọ'rin ìwúrí Mo mà d'óko òwò mi, mo wà ní'bi iṣẹ' Mo pàdé ọdọ, mo mà r'ọmọdé níbẹ' o, pẹ'l'ágbàlagbà L'ọ'kùnrin, l'óbìnrin Mo r'ẹ'ni tí ń ronú, mo r'ẹ'ni tí ń bẹ'rù Mo r'ẹni tí ń gbọn l'ẹsẹ, t'ó ń ṣiyèméjì Ma fi sùúrù kẹ wọn, ma tọ wọn s'ọnà Mo mí kọ'rin ìgboyà Mo mí kọ'rin ìṣítí Mo ní Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ Ṣe kíá-kíá, yára bóóde, ògo mà mí pè wá o Ẹyẹ méjìlá, l'órí igi, l'étí fèrèsé ilé mi Wọn mí kọ'rin, l'òwúrọ' tí mo jí Wọn mí kọ'rin ayọ' Wọn mí kọ'rin ìwúrí Wọn ní Ṣe gírí, múra jáde, òní mà ládùn púpọ Ṣe kíá-kíá, yára bóóde o, ire mà mí pè ọ' o Ṣe gírí, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ Wọn ni, Ṣé kíá-kíá, yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o Wọn ni, Ṣé gírí, múra jáde, múra jáde o, òní mà ládùn púpọ Ṣe kíá-kíá, wọn ni, Yára bóóde, yára bóóde, ire mà mí pè ọ o Wọn ní, wọn ni, Ṣé gírí, ani o múra jáde, múra jáde, òní mà ládùn púpọ Ṣe kíá-kíá, ani o yára bóóde o, ogo wa mí pè wa o Mura jade Mura jade Yára bóóde

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band の他の曲

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band →

関連歌詞