Moriamo
YO

Moriamo 가사

장르Afrobeats
원문 언어YO
조회수20
Aa읽기 설정
글자 크기 18

원문 가사

YO
번역이 아직 없습니다. 원문 가사를 표시합니다.
Ọmọ Adefi Ọmọ Adefa lókè Iresi (Moriamo Alege) (Moriamo) Ìyá bàbá mí, sún re Ní ilé àyé, 1980 something (The Beat Handle) Damilare, èmi l'àkọ́bí bàa mi, kí Qudus tó dì Qdot Ìyá àti bàbá mí tí Jáà ó tí pẹ Kín tó wa'yé lótí ní wọn le fẹ'ra wọn Okun ẹbí t'oba Jáà, welder kàn ó lé jo (Alagbe) K'Ọlọrun f'ọrun kẹ Moriamo, ìyá bàbá mí Moriamo, ọmọ Alege Ìyá má ń gb'ọmọ gẹ-gẹ ní Màmá ó gbé mí sílẹ̀ k'èyàn kan-kan tọju mí Moriamo, ọrun re Mí ó gbàgbé okò Alado o, l'ọnà Erugbabu Okò obi yí grandma tí fọ lójú kàn Bóyà ń torí obi tó mà tá ní muri kàn Ìyá yí tún padà s'oko, ada, t'ohun t'ọkọ ní Orí mí à wú to bà pé mí lọkọ' mí Ọjọ rí jẹ, pẹlú ọjọ rírí mú Màmá ma ń r'oka pẹlú ẹfọ Bọkọlu Omi odò là má ń mú (omi odò là má ń mú) Labúlé Ado, labúlé Ado oh (labúlé Ado) (Abúlé Ado) abúlé wá ó jìnà si Shagamu À ńpadà s'oko ní motor jamu (ó má ṣée) Màmá bà ń pariwo: Damilare, ọmọlọmọ ní, ẹ bà ń gbé Ó mà ṣeé, ó mà ṣee (ó mà ṣeé) Ọjọ yẹn ní mo mọ pé ìyá yí kọ lo bí mí Moriamo Alege (Moriamo) Moriamo Alege (Moria oh) Moriamo Alege, ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ Moriamo Alege (Moriamo) Moriamo Alege (Moria oh) Moriamo Alege Ìyá bàbá mí, ọrun rè rẹ (Moriamo) Ọrun re rẹ (Moria oh) Hmm, ọjọ re bí ana nígbà t'ikú wọlé dé Ìyá yí tí r'ikú lóṣe ní ń b'ode lọ K'ojú mí mà bà r'ibi Rafiu, àbúrò mí ń gbà bọọlu nítá Mo wọlé padà, màmá tí d'ojú bo'lẹ Kàyéfì lójẹ', mo sáré pé bàbá mí Adio, ó bà dákún, wá wó màmá rẹ À ṣé ọlọjọ lódé o Ńgbà t'ariwo tá, lo ńbí wà, Kílódé? Kín to mọ, ẹsẹ tí pé Shifau, pẹ'lú Mutairu béèrè sí ńké (omijé oh) Wọn ní wọn ó le sìn màmá Moní, Kílódé? Wọn ní, Ẹmí ó jáde tán (ahh) Kòfẹ fimí silẹ lọ ní Ọjọ ìkíni lọ, ìkejì lọ Ọjọ ìkẹta, Moria dágbere fún'ayé Moriamo Alege (Moriamo) Moriamo Alege (Moria oh) Moriamo Alege Ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ Moriamo Alege (Moriamo) Moriamo Alege (Moriamo) Moriamo Alege Ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ (Moriamo) Ọrun re rẹ (Moriamo oh) Moria dàgbere fún ayé Odi'gbà, odi'gbere (Moriamo) Mama Shifau, Mama Mutairu Moriamo, ọmọ Alege, ọrun re rẹ Mà ro'yin ẹ f'ọmọ mí (Moriamo oh) Moriamo (Moriamo), Moriamo oh Moriamo (Moriamo) Moriamo Alege Yeah, who's here?

Qdot의 다른 곡

Qdot →

관련 가사